Yoruba - The Book of Prophet Zephaniah

Page 1

Sefaniah

ORI 1

1 ỌRỌ Oluwa ti o tọ Sefaniah wá, ọmọ Kuṣi, ọmọ Gedaliah, ọmọ Amariah, ọmọ Hiskiah, li ọjọ Josiah, ọmọ Amoni, ọba Juda.

2 Emi o run ohun gbogbo patapata kuro lori ilẹ, li Oluwa wi.

3 Emi o run enia ati ẹranko; Emi o run awọn ẹiyẹ oju-ọrun, ati ẹja okun, ati ohun ikọsẹ pẹlu awọn enia buburu; emi o si ke enia kuro ni ilẹ na, li Oluwa wi.

4 Emi o si na ọwọ mi si Juda, ati sori gbogbo awọn olugbe Jerusalemu; emi o si ke iyokù Baali kuro nihinyi, ati orukọ Kemarimu pẹlu awọn alufa;

5 Ati awọn ti nsìn ogun ọrun lori awọn ile; ati awọn ti nsìn ati awọn ti o fi Oluwa bura, ati awọn ti o fi Malkamu bura;

6 Ati awọn ti o yipada kuro lọdọ Oluwa; ati awọn ti kò wá Oluwa, bẹni nwọn kò si bère lọwọ rẹ.

7 Pa ẹnu rẹ mọ niwaju Oluwa Ọlọrun: nitoriti ọjọ Oluwa kù si dẹdẹ: nitoriti Oluwa ti pèse ẹbọ, o ti pè awọn alejo rẹ.

8 Yio si ṣe li ọjọ ẹbọ Oluwa, li emi o jẹ awọn ijoye, ati awọn ọmọ ọba, ati gbogbo awọn ti o wọ li aṣọ àjeji.

9 Li ọjọ kanna pẹlu li emi o jẹ gbogbo awọnti nfò ni iloro, ti o kún ile oluwa wọn pẹlu iwa-ipa ati ẹtan.

10 Yio si ṣe li ọjọ na, li Oluwa wi, ariwo ẹkún yio ti ẹnu ibode ẹja wá, ati igbe lati ihà keji wá, ati ipakà nla lati awọn òke wá.

11 Ẹ hu, ẹnyinolugbeMakteṣi, nitoritiatikegbogbo awọn oniṣòwo lulẹ; gbogbo awọn ti o ru fadaka ni a ke kuro.

12. Yio si ṣe li akokò na, ti emi o fi fitila wá Jerusalemu wò, emi o si jẹ awọn ọkunrin ti o joko lori ibu wọn wò: ti nwi li ọkàn wọn pe, Oluwa kì yio ṣe rere, bẹni kì yio ṣe buburu.

13 Nitorina li ọrọ wọn yio di ikogun, ati ile wọn yio diahoro: nwọn o kọ ile pẹlu, ṣugbọn nwọnkì yio gbe inu wọn; nwọn o si gbìn ọgbà-àjara, ṣugbọn nwọn kì yio mu ọti-waini rẹ

14 Ọjọ nla Oluwa kù si dẹdẹ, o kù si dẹdẹ, o si yara gidigidi, ani ohùn ọjọ Oluwa: alagbara ọkunrin yio kigbe kikoro nibẹ.

15 Ọjọ náà jẹ ọjọ ìbínú,ọjọ ìdààmú àti ìdààmú,ọjọ ìsọdahoro àti ìsọdahoro,ọjọ òkùnkùn àti ìṣúdùdù,ọjọ ìkùukùu àti òkùnkùn biribiri.

16 Ọjọ ipè ati idagiri si ilu olodi, ati si awọn ile-iṣọ giga.

17 Emi o si mu ipọnju wá sori enia, ti nwọn o ma rìn biafọju, nitoritinwọntiṣẹ siOluwa: a o sita ẹjẹ wọn silẹ bi ekuru, ati ẹran-ara wọn bi igbẹ.

18 Fadaka tabi wurà wọn kì yio le gbà wọn li ọjọ ibinu Oluwa; ṣugbọn iná owú rẹ li a o fi run gbogbo ilẹ na: nitoriti yio yara mu gbogbo awọn ti ngbe ilẹ na run.

ORI 2

1 Ẹ kó ara nyin jọ, nitõtọ, ẹ ko ara nyin jọ, ẹnyin orilẹ-ède ti kò fẹ;

2 Ki aṣẹ na to jade, ki ọjọ na to kọja bi iyangbo, ki ibinu kikanOluwato desorinyin, kiọjọ ibinuOluwa to de sori nyin.

3 Ẹ wá OLUWA, gbogbo ẹyin ọlọkàn tútù ayé, tí ẹ ti ṣe ìdájọ rẹ; ẹ wá ododo, ẹ wá ìwa tutu: bọya a o fi nyin pamọ li ọjọ ibinu Oluwa.

4 Nitoripe a o kọ Gasa silẹ, ati Aṣkeloni ni ahoro: nwọn o lé Aṣdodu jade li ọsán, a o si fà Ekroni tu.

5 Egbe ni fun awọn ti ngbe eti okun, orilẹ-ède awọn Kereti! ọrọ OLUWA lòdì sí yín; Iwọ Kenaani, ilẹ awọnFilistini, aniemio pa ọ run,tikì yio fisiolugbe.

6 Ati àgbegbe okun yio si jẹ ibujoko ati ile kekere fun awọn oluṣọ-agutan, ati agbo fun agbo-ẹran.

7 Ààlà náà yóò sì wà fún ìyókù ilé Júdà; nwọn o jẹun lori rẹ: ni ile Aṣkeloni ni nwọn o dubulẹ li aṣalẹ: nitori Oluwa Ọlọrun wọn yio bẹ wọn wò, yio si yi igbekun wọn pada.

8 Emi ti gbọ ẹgan Moabu, ati ẹgan awọn ọmọ Ammoni, nipa eyiti nwọn ti gàn awọn enia mi, ti nwọn si ti gbé ara wọn ga si àgbegbe wọn.

9 Nitorina bi emi ti wà, li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi, Nitõtọ Moabu yio dabi Sodomu, ati awọn ọmọ Ammoni yio dabi Gomorra, ati ibisi idọ, ati ọgbun iyọ, ati ahoro lailai: iyokù mi; enia yio si kó wọn, ati awọn iyokù ti awọn enia mi yio si gbà wọn.

10 Eyi ni nwọn o ni nitori igberaga wọn, nitoriti nwọn ti gàn, nwọn si ti gbé ara wọn ga si awọn enia Oluwa awọn ọmọ-ogun.

11 OLUWA yio si li ẹru fun wọn: nitoriti yio pa gbogbo oriṣa aiye li ebi; enia yio si ma sìn i, olukuluku lati ipò rẹ wá, ani gbogbo erekùṣu awọn keferi.

12 Ẹnyin ará Etiopia pẹlu, a o fi idà mi pa nyin.

13 On o si nà ọwọ rẹ si ariwa, yio si run Assiria; emi o si sọ Ninefe di ahoro, yio si gbẹ bi aginju. . ohùn wọn yoo kọrin ni awọn ferese; idahoro yio wà ni iloro: nitori on o tú iṣẹ kedari silẹ

15 Eyi ni ilu ayọ ti o joko li aisimi, ti o wi li ọkàn rẹ pe, Emi ni, kò si si ẹlomiran lẹhin mi: bawo ni o ṣe di ahoro, ibiti ẹranko dubulẹ si! olukuluku ẹniti o kọja lọdọ rẹ yio pò, yio si mì ọwọ rẹ.

ORI 3

1 EGBE ni fun ẹnitio diẽriatiaimọ, fun ilu aninilara!

2 On kò gbọ ohùn na; kò gba ìbáwí; on kò gbẹkẹle OLUWA; kò sún mọ Ọlọrun rẹ

3 Awọn ọmọ-alade rẹ ti ngbe inu rẹ li awọn kiniun ti nke ramuramu; Ìkookò alẹ ni àwọn onídàájọ rẹ; wọn kì í jẹ egungun títí di ọla.

. 5 Oluwa olododo mbẹ larin rẹ; on kì yio ṣe ẹṣẹ: li owurọ o mu idajọ rẹ wá si imọlẹ, kì yio yẹ; ṣugbọn awọn alaiṣõtọ kò mọ itiju.

6 Emi tike awọn orilẹ-ède kuro: ile-iṣọ wọndiahoro; Mo sọòpópónà wọndiahoro,tíẹnikẹnikò sìkọjá lọ: a pa àwọn ìlú wọn run, tí kò fi sí ẹnìkan, tí kò sí olùgbé.

7 Emi wipe, Nitõtọ iwọ o bẹru mi, iwọ o si gbà ẹkọ; bẹni ki a má ba ke ibugbe wọn kuro, bi mo ti jẹ wọn niya: ṣugbọn nwọn dide ni kùtukutu, nwọn si ba gbogbo iṣe wọn jẹ

8 Nitorina ẹ duro de mi, li Oluwa wi, titi di ọjọ ti emi o dide si ijẹ: nitori ipinnu mi ni lati ko awọn orilẹède jọ, ki emi ki o le ko awọn ijọba jọ, lati da irunu mi sori wọn, ani gbogbo ibinu gbigbona mi sori wọn. : nitori gbogbo aiye li a o fi iná owú mi run.

9 Nitori nigbana li emi o yi ede mimọ pada si awọn enia, ki gbogbo wọn ki o le ma kepè orukọ Oluwa, ki nwọn ki o le ma sìn i pẹlu ifọkansi kan.

10 Láti òdìkejì odò Etiópíà ni àwọn olùbẹbẹ mi, àní ọmọbìnrin tí a fọnká mi, yóò mú ọrẹ mi wá.

11 Li ọjọ na li oju kì yio tì ọ nitori gbogbo iṣe rẹ, ninu eyiti iwọ ti ṣẹ si mi: nitori nigbana li emi o mu kuro lãrin rẹ awọn ti nyọ ninu igberaga rẹ, iwọ kì yio si gberaga mọ nitori mi. oke mimọ.

12 Emi o si fi talaka atitalaka enia silẹ lãrinrẹ, nwọn o si gbẹkẹle orukọ Oluwa.

13 Awọn iyokù Israeli kì yio ṣe aiṣedede, bẹni kì yio sọrọ eke; bẹni a kì yio ri ahọn ẹtan li ẹnu wọn: nitori nwọn o jẹun, nwọn o si dubulẹ, kò si si ẹniti yio dẹruba wọn.

14 Kọrin, iwọ ọmọbinrin Sioni; kígbe, ìwọ Ísírẹlì; yọ, ki o si yọ pẹlu gbogbo ọkàn, iwọ ọmọbinrin Jerusalemu.

15 Oluwa ti mu idajọ rẹ kuro, o ti lé ọta rẹ jade: ọba Israeli, ani Oluwa, mbẹ lãrin rẹ: iwọ kì yio si ri ibi mọ.

16 Liọjọ na liao wifunJerusalemu pe, Iwọ mábẹru: ati fun Sioni pe, Máṣe jẹ ki ọwọ́ rẹ ki o rẹ

17 OLUWA Ọlọrun rẹ li agbara li ãrin rẹ; on o gbà, yio si yọ lori rẹ pẹlu ayọ; yio simi ninu ife re, yio fi orin dun lori re.

18 N óo kó àwọn tí wọn ní ìbànújẹ ní àpéjọ mímọ jọ,àwọn tí wọn jẹ tìrẹ,àwọn tí ẹgàn rẹ ti di ẹrù.

19 Kiyesi i, li akokò na li emi o mu gbogbo awọn ti npọn ọ loju kuro: emi o si gbà ẹniti npa ọgbẹ là, emi

o si kó ẹniti a le jade; èmi yóò sì gba ìyìn àti òkìkí ní gbogbo ilẹ tí ojú ti tì wọn. 20 Li akoko na li emi o tun mu nyin pada wá, ani li akokò ti emi o kó nyin jọ: nitori emi o ṣe nyin li orukọ ati iyìn lãrin gbogbo enia aiye, nigbati mo ba yi igbekun nyin pada li oju nyin, li Oluwa wi.

Turn static files into dynamic content formats.

Create a flipbook
Issuu converts static files into: digital portfolios, online yearbooks, online catalogs, digital photo albums and more. Sign up and create your flipbook.